- 1. 2000 ní òǹkà Yorùbá ni___
A) Ẹgbàá B) Ẹgbẹrun C) Ogún D) Ẹgbàá rin
- 2. Kí ni 20,000 ní òǹkà Yorùbá?
A) Ẹgbàá wà B) Ẹgbàafà C) Ẹgbarun D) Ẹgbàá je
- 3. Ohun tí kò tọ́ tí a ṣe sí ọmọlàkejì ni ìwà___
A) Ọ̀sì B) Omolúàbí C) Ìdọ̀tí D) Ìkà
- 4. Ìwọ̀nyí ni ìwà ìkà tí ó wọ́pọ̀ ni ayé àtijọ́ àyàfi___
A) Ìfiniṣọfà B) Ìfinirúbọ C) Ìfiniṣẹrú D) Ìfọmọṣowó
- 5. Ìwà ìkà tí o wọ́pọ̀ lóde òní ni ìwọ̀nyí, àyàfi___
A) Ìfiniṣọfà B) Lílo ọmọ nílọ̀kulọ̀ C) Ìfiniṣowó D) Ìjínigbé
- 6. Ọ̀rọ̀____lè ṣiṣẹ́ olùwà,ẹ̀yán, àti àbọ̀.
A) ìṣẹ B) Orúkọ C) àpónlé D) àpèjúwe
- 7. ____ ni àwọn Yorùbá gbà pé wọ́n ń sọ ọjà di ọ̀wọ́n.
A) Èrò ọjà B) Oníbárà C) Alágbàtà D) Ọlójà
- 8. À n ṣe òwò kí á le____
A) sọ́ọ̀tì B) di ìyálọ́jà C) ríhun ṣe D) jẹ èrè
- 9. Àǹfààní òwò ṣiṣe níwònyí àyàfi; Ó ń mú ____
A) ẹni di ọ̀lẹ B) kí ìṣẹ́ àti òṣì pòórá C) kí a níṣẹ́ ẹni lọ́wọ́ D) kí a tẹpá mọ́ṣẹ́
- 10. ____tàbí káràkátà jẹ́ ọ̀kan nínú ara iṣẹ owó Yoruba.
A) Oúnjẹ jíjẹ B) Òwò ṣíṣe C) Aróbọ̀ D) Ìwà òtítọ́
- 11. Ẹni tí ó ta ọjà tí kò jèrè ni won ní o____
A) ṣòwò sọ́ọ̀ti B) tẹpá mọ́ṣẹ́ C) tàtà jèrè D) gbìyànjú
- 12. Ìwòyí ni iṣẹ tí ọ̀rọ̀ orúkọ le ṣe,ayafi____
A) òpómúléró B) olùwà C) àbọ̀ D) ẹ̀yán
- 13. 'Bàbá Bọ́lá lọ sí oko'. Kí ni ọrọ orúkọ tí o se iṣẹ́ ẹ̀yán nínú gbólóhùn yìí?
A) lọ B) Oko C) Bọ́lá D) Bàbá
- 14. Èwo ni kìí ṣe álífábẹ̀ẹ̀tì ede Yorùbá
A) ae B) a C) o D) b
- 16. Àmì wo ni ó bá ọ̀rọ̀ yí mu? kirakita--d:d:d:d
A) kirákíta B) kirakitā C) Kìrákítà D) Kìràkìtà
- 17. Àmì wo ni ó bá ọ̀rọ̀ yí mu? Dodo--d:d
A) Dódó B) Dọ̀dó C) Dodo D) Dòdò
- 18. Fáwẹ̀lì Yorùbá pín sí:
A) àfúnupè àti aṣẹ́nupè B) àìgbẹ̀fẹ̀ àti agbẹ̀fẹ̀ C) arẹ́họ́n ati àkùnyùn D) àìránmúpè ati àrańmúpè
- 19. Tọ́ka sí ọ̀rọ̀-orúkọ olùwà nínú gbólóhùn yìí: "Ajá bàbá Olú tí jẹ ẹja náà"
A) Ajá B) bàbá C) náà D) Olú
- 20. "Ojó lọ ra ẹja tí yóò jẹ" Tọ́ka sí ọ̀rọ̀-orúkọ àbọ̀ nínú gbólóhùn yìí.
A) ra B) ẹja C) Ojo D) lọ
- 21. "Adébísí pa ẹran màálu jẹ". Èwo ni ọ̀rọ̀-orúkọ tí ó ṣiṣé ẹ̀yán nínú gbólóhùn yìí?
A) Adébísí B) màálu C) ẹran D) pa
- 22. Kí a tó lè di oníṣòwò,a gbọ́dọ̀ ní nǹkan wọnyí àyàfi____.
A) ní ìmọ̀ nípa ọjà ta fẹ tà B) ìdọmọ ẹgbẹ́ ọlọ́jà C) owó òkòwò D) ẹ̀kọ́sẹ́ kátà-kárà
- 23. Fífún òǹràjà ní díẹ̀ jẹ nínú ọjà tí à ń tà ni à ń pè ní_____.
A) sàn díẹ̀díẹ̀ B) àwín C) ènì D) ìtọ́wọ̀
- 24. Ìwọ̀nyí ni àwọn owó tí a mọ àwọn Yorùbá sì àyàfi_____.
A) Aróbọ̀ B) Owóróbo C) Ìjínigbé D) Aṣọ títa
- 25. ______ni à ń pe àwọn tí n ta ọjà pẹ́ẹ́pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ́.
A) Alájàpá B) Olóúnjẹ C) Oníwóróbo D) Aláróbò
- 26. Ọ̀rọ̀ orúkọ inú gbólóhùn yìí "Motúnráyọ̀ sì tún rápálá wọlé" ni:
A) wọlé B) Motúnráyọ̀ C) si D) tun
- 27. Kọ́ńsónáǹtì tó wà nínú èdè Yorùbá jẹ_____
A) 18 B) 10 C) 17 D) 9
- 28. Èwo ni kọ́ńsónáǹtì tí a fi èjì ètè pè nínú àwọn wọ̀nyí?
A) d B) g C) b D) f
- 29. ___jẹ́ fáwẹ̀lì àyanupẹ̀
A) a B) u C) m D) n
- 30. ___jẹ kọ́ńsónáǹtì àrańmúpè.
A) p B) t C) s D) n
|