- 1. Mélòó ni álífábẹ̀ẹ̀tì konsonanti èdè Yorùbá?
A) 20 B) 11 C) 15 D) 18
- 2. 2000 ní òǹkà Yorùbá ni____
A) Ogójì B) Egbèje C) Ẹgbẹ̀waa D) Ọgbọ̀n
- 3. _____ni orísirísi ọ̀rọ̀ tí à ń lò nínú gbólóhùn
A) òwe B) gbólóhùn C) Ìsòrí ọ̀rọ̀ D) ewì
- 4. Ọ̀rọ̀ tó ń ṣiṣẹ́ Olùwà,àbọ̀, àti ẹ̀yán nínú gbólóhùn èdè Yorùbá ni___
A) Ọ̀rọ̀ orúkọ B) Ọ̀rọ̀ àpónlé C) Ọ̀rọ̀ àpèjúwe D) Ọ̀rọ̀ ìṣe
- 5. Ojú àti imú ń dùn mi. Èwo ni ọ̀rọ̀ àsopọ nínú gbólóhùn yìí?
A) dùn B) oju C) àti D) imú
- 6. Ọnà mélòó ni álífábẹ̀ẹ̀tì èdè Yorùbá pín sí?
A) Márùn-ún B) Méjì C) Mẹ́rin D) Mẹ́ta
- 7. Lẹ́tà fáwẹ̀lì èdè Yorùbá ni_____
A) a,e,ẹ,i,o,ọ,u B) a,e,ẹ,y,z,u C) a,m,n,y,j,t D) b,d,g,gb,j,k,m
- 8. Òpómúléró inú gbólóhùn ni_____
A) Ọrọ orúkọ B) Ọ̀rọ̀ ìṣe C) Ọ̀rọ̀ onísílébù D) Ọ̀rọ̀ àpónlé
- 9. ____ni ọ̀ro tí ó ń tọ́ka sí ìṣèlẹ̀ tàbí ohun ti ẹnìkan ṣe nínú gbólóhùn.
A) Ọ̀rọ̀ àpónlé B) Ọ̀rọ̀ arọ́pò orúkọ C) Ọ̀rọ̀ ìṣe D) Ọ̀rọ̀ àpèjúwe
- 10. 'Mo wá sùgbọ́n ń kò ba yín'. Èwo ni ọ̀rọ̀ àsopọ nínú gbólóhùn yìí?
A) yín B) mo wá C) sùgbón D) ba
- 11. ____ ni àwọn ọ̀rọ̀ tí a fi ń so àwọn ọ̀rọ̀ orúkọ tàbí gbólóhùn pọ̀.
A) Ọ̀rọ̀ ìṣe B) Ọ̀rọ̀ atọ́kùn C) Ọ̀rọ̀ àsopọ̀ D) Ọ̀rọ̀ àpónlé
- 12. ____ni egbẹ̀rún ní òǹkà Yorùbá.
A) 3000 B) 10,000 C) 1000 D) 5000
- 13. _____ni àwọn ọ̀rọ̀ tí a fi ń so àwọn ọ̀rọ̀ orúkọ tàbí gbólóhùn pọ̀.
A) Ọ̀rọ̀ atọ́kùn B) Ọ̀rọ̀ àsopọ C) Ọ̀rọ̀ àpọ́nlé D) Ọ̀rọ̀ àpèjúwe
- 14. Kọ́ńsónáǹtì akọ́kọ́ nínú álífábẹ̀ẹ̀tì Yorùbá ni____
A) b B) a C) d D) z
- 15. Lẹ́tà tí ó parí álífábẹ̀ẹ̀tì Yorùbá ni___
A) e B) u C) i D) y
- 16. Álífábẹ̀ẹ̀tì Yorùbá tó wà ní ipò kárùn-ún ni____
A) gb B) b C) ẹ D) f
- 17. Wa ri mi ni Abuja. 'ni' nínú gbólóhùn yi jẹ ọ̀rọ̀____
A) iṣe B) atọ́kùn C) arọ́po orúkọ D) àpọ́nlé
- 18. Fáwẹ̀lì àkọ́kọ́ nínú álífábẹ̀ẹ̀tì Yorùbá ni____
A) o B) i C) ẹ D) a
- 19. Fáwẹ̀lì yìí kìí ṣe ti Yorùbá
A) o B) ea C) ọ D) i
- 20. "Fọláké pupa fòò". fòò nínú gbólóhùn yìí jẹ́ ọ̀rọ̀_____.
A) atọ́kùn B) àpọ́nle C) ẹ̀yán D) ìṣe
- 21. Ọ̀rọ̀-orúkọ àbọ̀ nínú gbólóhùn yìí: "Mo jẹ iyán tán" ni____
A) tan B) jẹ C) Iyan D) mo
- 22. Ọ̀rọ̀-orúkọ tí ó ṣiṣẹ́ ẹ̀yán nínú gbólóhùn yìí: "Ìyàwó Bísí wọ aṣọ òfì" ni____.
A) Bísí B) wọ C) aṣọ D) Ìyá
- 23. _____ni ọ̀rọ̀ tí ó ń tọ́ka iṣẹ tàbí ohun tí ẹnìkan ṣe nínú gbólóhùn.
A) Ọ̀rọ̀ orúkọ B) Ọ̀rọ̀ àpèjúwe C) Ọ̀rọ̀ àpọ́nlẹ́ D) Ọ̀rọ̀ ìṣe
- 24. Ọ̀rọ̀_____ ni a máa n lo rọ́pò ọ̀rọ̀ orúkọ.
A) àpèjúwe B) ìṣe C) àsopọ̀ D) arọ́pò orúkọ
- 25. "Aṣọ funfun ni ìyàwó wọ̀". _____ ni ọ̀rọ̀ àpèjúwe nínú gbólóhùn yìí.
A) Iyawo B) ni C) Aṣọ D) Funfun
- 26. Abi, sùgbọ́n, pẹ̀lú,àti,àmọ́ ni àwọn àpẹẹrẹ ọ̀rọ̀_____.
A) Atọ́kùn B) Àpèjúwe C) Arọ́pò D) Àsopọ
- 27. "Délé ti Ìbàdàn dé lánàá". ____jẹ ọ̀rọ̀ atókùn nínú gbólóhùn yìí
A) Délé B) ni C) lánàá D) ti
- 28. Bí____ kò bá sí nínú gbólóhùn, gbólóhùn bi kò lè ní ìtumọ̀ kíkún.
A) ọ̀rọ̀ orúkọ B) ọ̀rọ̀ ìṣe C) ọ̀rọ̀ àpèjúwe D) ọ̀rọ̀ atọ́kùn
|